Isikiẹli 35 BM

Ìyà Tí Ọlọrun óo Fi Jẹ Edomu

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ òkè Seiri, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí.

3 Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní,‘Wò ó! Mo lòdì sí ọ,ìwọ Òkè Seiri.N óo nawọ́ ibinu sí ọ,n óo sọ ọ́ di ahoro ati aṣálẹ̀.

4 N óo sọ àwọn ìlú rẹ di aṣálẹ̀ìwọ pàápàá yóo sì di ahoro;o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

5 “ ‘Nítorí pé ò ń fẹ́ràn ati máa ṣe ọ̀tá lọ títí, o sì fa àwọn ọmọ Israẹli fún ogun pa nígbà tí ìṣòro dé bá wọn, tí wọn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

6 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra pé, n óo fi ọ́ fún ikú pa, ikú yóo máa lépa rẹ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́; ikú yóo máa lépa ìwọ náà.

7 N óo sọ òkè Seiri di aṣálẹ̀ ati ahoro. N óo pa gbogbo àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ níbẹ̀.

8 N óo da òkú sí orí àwọn òkè ńláńlá rẹ, yóo kún. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òkè kéékèèké rẹ, ati gbogbo àwọn àfonífojì rẹ, ati gbogbo ipa odò rẹ. Òkú àwọn tí a fi idà pa ni yóo kúnbẹ̀.

9 N óo sọ ọ́ di ahoro títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú àwọn ìlú rẹ mọ́. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

10 “ ‘Nítorí ẹ̀yin ará Edomu sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè mejeeji wọnyi ati ilẹ̀ wọn yóo di tiyín ati pé ẹ óo jogún rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA wà níbẹ̀.

11 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín.

12 Ẹ óo mọ̀ pé èmi OLUWA gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ ń sọ sí àwọn òkè Israẹli, pé wọ́n ti di ahoro ati ìkógun fun yín.

13 Ẹ̀ ń fi ẹnu yín sọ̀rọ̀ ìgbéraga sí mi, ẹ sì ń dá àpárá lù mí; gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’ ”

14 OLUWA Ọlọrun ní, “N óo sọ ìwọ Edomu di ahoro, kí gbogbo ayé lè yọ̀ ọ́;

15 bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”