Isikiẹli 28 BM

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Ọba Tire

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa,

3 nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú.

4 Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ.

5 O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’

6 “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Nítorí pé o ka ara rẹ kún ọlọ́gbọ́n bí àwọn oriṣa,

7 n óo kó àwọn àjèjì wá bá ọ; àwọn tí wọ́n burú jù ninu àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì gbógun tì ọ́, wọ́n yóo sì ba ẹwà ati ògo rẹ jẹ́, pẹlu ọgbọ́n rẹ.

8 Wọn óo tì ọ́ sinu ọ̀gbun; o óo sì kú ikú ogun láàrin omi òkun.

9 Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.

10 Ikú aláìkọlà ni o óo kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Ìṣubú Ọba Tire

11 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

12 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan.

13 O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ.

14 Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.

15 O péye ninu gbogbo ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dá ọ títí di ìgbà tí a rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.

16 Ninu ọpọlọpọ òwò tí ó ń ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà jàgídíjàgan, o sì dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà mo lé ọ jáde bí ohun ìríra kúrò lórí òkè Ọlọrun. Kerubu tí ń ṣọ́ ọ sì lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.

17 Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba.

18 O ti fi ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí o dá nítorí ìwà aiṣootọ ninu òwò rẹ, ba ibi mímọ́ mi jẹ́. Nítorí náà, mo jẹ́ kí iná ṣẹ́ ní ààrin rẹ; ó sì jó ọ run; mo sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ ayé lójú gbogbo àwọn tí ń wò ọ́.

19 Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́ láàrin àwọn eniyan láyé ni ó yà lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí ọ. Òpin burúkú ti dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́ títí ayé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Sidoni

20 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

21 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Sidoni, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé

22 OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni. N óo sì fi ògo mi hàn láàrin rẹ. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ; tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn wọ́n.

23 Nítorí n óo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá ọ jà n óo sì jẹ́ kí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ní ìgboro rẹ. Àwọn tí wọ́n yí ọ ká yóo gbógun tì ọ́, wọn óo sì fi idà pa ọpọlọpọ eniyan ninu rẹ,’ nígbà náà o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

A óo Bukun Israẹli

24 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ti ilé Israẹli, kò ní sí ọ̀tá tí yóo máa ṣe ẹ̀gún gún wọn mọ́, láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká tí wọ́n sì ń kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

25 “Nígbà tí mo bá kó àwọn ará ilé Israẹli jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin wọn, lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, wọn óo máa gbé ilẹ̀ tiwọn, ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi.

26 Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.”