Isikiẹli 40 BM

ÌRAN NÍPA TẸMPILI ỌJỌ́ IWÁJÚ

Isikiẹli Lọ sí Jerusalẹmu Lójú Ìran

1 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni, ọdún kẹẹdọgbọn tí a ti wà ní ìgbèkùn, tíí ṣe ọdún kẹrinla tí ogun fọ́ ìlú Jerusalẹmu, agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi.

2 Ó mú mi lọ sí ilẹ̀ Israẹli ninu ìran, ó gbé mi sí orí òkè gíga kan. Ó dàbí ẹni pé ìlú kan wà ní ìhà ìsàlẹ̀ òkè náà.

3 Nígbà tí ó mú mi dé ìlú náà, mo rí ọkunrin kan tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí idẹ. Ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà, ó mú okùn òwú ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń wọn nǹkan lọ́wọ́.

4 Ọkunrin yìí bá pè mí, ó ní: “ìwọ ọmọ eniyan, ya ojú rẹ, kí o máa wòran, ya etí rẹ sílẹ̀, kí o máa gbọ́; sì fi ọkàn sí gbogbo ohun tí n óo fihàn ọ́; nítorí kí n baà lè fihàn ọ́ ni a ṣe mú ọ wá síbí. Gbogbo ohun tí o bá rí ni o gbọdọ̀ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

Ibodè Ìlà Oòrùn

5 Mo rí ògiri kan tí ó yí ibi tí tẹmpili wà ká. Ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọkunrin tí mo kọ́ rí gùn ní igbọnwọ mẹfa. Igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ọ̀pá tirẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, (ìdajì mita kan). Ó sì wọn ògiri náà. Ó fẹ̀ ní ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ kan, ó sì ga ní ọ̀pá kan, (mita 3).

6 Lẹ́yìn náà ó lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ó gun àtẹ̀gùn tí ó wà níbẹ̀, ó sì wọn àbáwọlé ẹnu ọ̀nà náà; ó jìn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, (mita 3).

7 Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà gùn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, wọ́n sì fẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pá kan. Àlàfo tí ó wà láàrin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½). Àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ẹ̀bá ìloro tí ó kọjú sí tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan.

8 Lẹ́yìn náà ó wọn ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, ó jẹ́ igbọnwọ mẹjọ (mita 4),

9 àtẹ́rígbà rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, mita kan. Ìloro ẹnu ọ̀nà náà wà ninu patapata.

10 Yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnu ọ̀nà náà. Bákan náà ni ìwọ̀n àwọn yàrá mẹtẹẹta rí. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwọ̀n àtẹ́rígbà wọn, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji.

11 Lẹ́yìn náà, ó wọn ìbú àbáwọlé ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5). Ó wọn gígùn ẹnu ọ̀nà náà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹtala (mita 6½).

12 Ògiri kan wà níwájú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà, ó ga ní igbọnwọ kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Ati òòró ati ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa mẹfa (mita 3).

13 Ó wọn ẹnu ọ̀nà náà láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ kan títí dé ẹ̀yìn yàrá ẹ̀gbẹ́ keji, ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), láti ìlẹ̀kùn kinni sí ekeji.

14 Ó tún wọn ìloro, ó jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Gbọ̀ngàn kan yí ìloro ẹnu ọ̀nà ká

15 láti iwájú ẹnu ọ̀nà ní àbáwọlé, títí kan ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25).

16 Ẹnu ọ̀nà náà ní àwọn fèrèsé tóóró tóóró yíká, tí ó ga kan àwọn àtẹ́rígbà àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́. Bákan náà, ìloro náà ní àwọn fèrèsé yíká, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀.

Gbọ̀ngàn Òde

17 Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn ti òde, mo rí àwọn yàrá ati pèpéle yíká àgbàlá náà. Ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára àgbàlá náà.

18 Pèpéle kan wà níbi ẹnu ọ̀nà, tí gígùn rẹ̀ rí bákan náà pẹlu ẹnu ọ̀nà, èyí ni pèpéle tí ó wà ní ìsàlẹ̀.

19 Ó wọn ibẹ̀ láti inú ẹnu ọ̀nà kúkúrú títí dé iwájú ìta gbọ̀ngàn inú, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, (mita 45), ní ìhà ìlà oòrùn ati ìhà àríwá.

Ẹnu Ọ̀nà Ìhà Àríwá

20 Lẹ́yìn náà, ó ṣiwaju mi lọ sí ìhà àríwá; ó wọn ìbú ati òòró ẹnu ọ̀nà kan tí ó wà níbẹ̀ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, tí ó sì ṣí sí àgbàlá òde.

21 Àwọn yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀ rí bákan náà pẹlu àwọn ti ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

22 Àwọn fèrèsé rẹ̀, ati ìloro rẹ̀ ati àwọn àwòrán ọ̀pẹ ara rẹ̀ rí bíi àwọn ti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ sì wà ninu.

23 Níwájú ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ni ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú wà bí ó ti wà níwájú ẹnu ọ̀nà ti ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wọn ibẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà kan sí ikeji, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

Ẹnu Ọ̀nà Ìhà gúsù

24 Ó mú mi lọ sí apá ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan níbẹ̀. Ó wọn àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀, wọ́n sì rí bákan náà pẹlu àwọn yòókù.

25 Fèrèsé yí inú ati ìloro rẹ̀ ká, bíi àwọn fèrèsé ti àwọn ẹnu ọ̀nà yòókù. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

26 Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ wà ninu, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji.

27 Ẹnu ọ̀nà kan wà ní ìhà gúsù gbọ̀ngàn inú. Ó wọn ibẹ̀, láti ẹnu ọ̀nà náà sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà gúsù, jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

Gbọ̀ngàn Inú: Ẹnu Ọ̀nà Ìhà gúsù

28 Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn inú, lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà náà, bákan náà ni òòró ati ìbú rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù.

29 Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. Fèrèsé wà lára rẹ̀ yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

30 Àwọn ìloro wà yí i ká, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), wọ́n sì fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un (mita 2½).

31 Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

Gbọ̀ngàn Inú: Ẹnu Ọ̀nà Ìlà Oòrùn

32 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìhà ìlà oòrùn gbọ̀ngàn inú, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, bákan náà ni ó rí pẹlu àwọn yòókù.

33 Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ati àtẹ́rígbà, ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, fèrèsé wà lára òun náà yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

34 Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

Gbọ̀ngàn Inú: Ẹnu Ọ̀nà Àríwá

35 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ibi ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá, ó sì wọ̀n ọ́n, bákan náà ni òun náà rí pẹlu àwọn yòókù.

36 Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

37 Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

Àwọn Ilé tí ó Wà Lẹ́bàá Ẹ̀gbẹ́ Ẹnu Ọ̀nà Àríwá

38 Yàrá kan wà tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ninu ìloro ẹnu ọ̀nà, níbẹ̀ ni wọ́n tí ń fọ ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun.

39 Tabili meji meji wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà, lórí wọn ni wọ́n tí ń pa àwọn ẹran ẹbọ sísun, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

40 Tabili meji wà ní ìta ìloro náà, ní ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá, tabili meji sì tún wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà.

41 Tabili mẹrin wà ninu, mẹrin sì wà ní ìta, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà; gbogbo rẹ̀ jẹ́ tabili mẹjọ. Lórí wọn ni wọ́n tí ń pa ẹran ìrúbọ.

42 Tabili mẹrin kan tún wà tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ìbú rẹ̀ náà jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ó sì ga ní igbọnwọ kan (bíi ìdajì mita). Lórí rẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran ẹbọ sísun ati ti ẹbọ yòókù sí.

43 Wọ́n kan àwọn ìkọ́ kan tí ó gùn ní ìwọ̀n àtẹ́lẹwọ́ kan mọ́ ara tabili yíká ninu. Wọn a máa gbé ẹran tí wọn yóo bá fi rúbọ lé orí àwọn tabili náà.

44 Lẹ́yìn náà ó mú mi wọ gbọ̀ngàn ti inú. Mo rí yàrá meji ninu gbọ̀ngàn yìí: ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ó dojú kọ ìhà gúsù, ekeji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìhà gúsù, ó dojú kọ ìhà àríwá.

45 Ó wí fún mi pé àwọn alufaa tí ń mójútó tẹmpili ni wọ́n ni yàrá tí ó kọjú sí ìhà gúsù.

46 Yàrá tí ó kọjú sí ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn alufaa tí wọn ń mójútó pẹpẹ; àwọn ni àwọn ọmọ Sadoku. Àwọn nìkan ninu ìran Lefi ni wọ́n lè súnmọ́ OLUWA láti rúbọ sí i.

Gbọ̀ngàn Inú ati Tẹmpili

47 Ó wọn gbọ̀ngàn ti inú, òòró rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45), igun rẹ̀ mẹrẹẹrin dọ́gba, pẹpẹ sì wà níwájú tẹmpili.

48 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìloro tẹmpili, ó sì wọn àtẹ́rígbà rẹ̀. Ó jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un (mita 2½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji; ìbú ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita 7). Àwọn ògiri rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta mẹta (mita 1½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji.

49 Òòró ìloro náà jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita 5½), àtẹ̀gùn rẹ̀ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, òpó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ́rígbà rẹ̀.