1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
3 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
4 Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn.
5 Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde.
6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.”