Isikiẹli 16:37-43 BM

37 Wò ó! N óo kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ, tí inú rẹ dùn sí jọ, ati àwọn tí o fẹ́ràn ati àwọn tí o kórìíra, ni n óo kó wá láti dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà. N óo tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, kí wọ́n lè rí ìhòòhò rẹ.

38 N óo ṣe ìdájọ́ fún ọ bí wọn tí ń ṣe ìdájọ́ fún àwọn obinrin tí wọ́n kọ ọkọ sílẹ̀, tabi àwọn tí wọ́n paniyan. N óo fi ìtara ati ibinu gbẹ̀san ìpànìyàn lára rẹ.

39 N óo fi ọ́ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn óo wó ilé oriṣa ati ibi ìrúbọ rẹ palẹ̀. Wọn óo tú aṣọ rẹ, wọn óo gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò.

40 “Wọn óo kó àwọn ọmọ ogun wá bá ọ, wọn óo sọ ọ́ lókùúta, wọn óo sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́.

41 Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́.

42 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára rẹ, n kò sì ní jowú nítorí rẹ mọ́. Ara mi yóo rọlẹ̀, inú kò sì ní bí mi mọ́.

43 Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.