Isikiẹli 16:41-47 BM

41 Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́.

42 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára rẹ, n kò sì ní jowú nítorí rẹ mọ́. Ara mi yóo rọlẹ̀, inú kò sì ní bí mi mọ́.

43 Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

44 OLUWA ní: “Gbogbo eniyan ni yóo máa pa òwe yìí mọ́ ìwọ Jerusalẹmu pé: ‘Òwú ìyá gbọ̀n ni ọmọ óo ran, bí ìyá bá ti rí ni ọmọ rẹ̀ obinrin yóo rí.’

45 Ọmọ bíbí inú ìyá rẹ ni ọ́, tí kò bìkítà fún ọkọ ati àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà kan náà ni ó wà lọ́wọ́ ìwọ ati àwọn arabinrin rẹ, àwọn náà kò ka ọkọ ati àwọn ọmọ wọn sí. Ará Hiti ni ìyá rẹ, ará Amori sì ni baba rẹ.

46 “Samaria ni ẹ̀gbọ́n rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà àríwá. Sodomu ni àbúrò rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà gúsù.

47 Títẹ̀lé ìṣe wọn nìkan kò tẹ́ ọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe ohun ìríra bíi tiwọn kò tó ọ. Láìpẹ́ ọjọ́, ìwà tìrẹ gan-an yóo burú ju tiwọn lọ.