Isikiẹli 16:51-57 BM

51 “Ẹ̀ṣẹ̀ tí Samaria dá kò tó ìdajì èyí tí ìwọ dá, ohun ìríra tí o ṣe sì jù tiwọn lọ. O ti mú kí arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí pé nǹkan ìríra tí o ṣe pọ̀ pupọ ju tirẹ̀ lọ.

52 Ó yẹ kí ojú ti ìwọ pàápàá, nítorí o ti jẹ́ kí ìdájọ́ gbe àwọn arabinrin rẹ, nítorí nǹkan ìríra tí o ṣe ju tiwọn lọ. Ọ̀nà wọn tọ́ ju tìrẹ lọ, nítorí náà, ó yẹ kí ojú tì ọ́, nítorí o ti mú kí àwọn arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.”

53 OLUWA sọ níti Jerusalẹmu pé, “N óo dá ire wọn pada: ire Sodomu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ati ire Samaria ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin. N óo dá ire tìrẹ náà pada pẹlu tiwọn.

54 Kí ojú lè tì ọ́ fún gbogbo ohun tí o ṣe tí o fi dá wọn lọ́kàn le.

55 Ní ti àwọn arabinrin rẹ: Sodomu ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, Samaria ati àwọn ọmọ rẹ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin náà yóo pada sí ibùgbé yín.

56 Ṣebí yẹ̀yẹ́ ni ò ń fi Sodomu arabinrin rẹ ṣe ní àkókò tí ò ń gbéraga,

57 kí ó tó di pé àṣírí ìwà burúkú rẹ wá tú? Nisinsinyii ìwọ náà ti dàbí rẹ̀; o ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Edomu ati àwọn tí ó wà ní agbègbè wọn, ati lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Filistini, ati àwọn tí wọ́n yí ọ ká, tí wọn ń kẹ́gàn rẹ.