32 OLUWA Ọlọrun ní:“ọpọlọpọ ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ọ́,wọn óo fi ọ́ rẹ́rìn-ín,wọn óo sì fi ọ́ ṣẹ̀sín,nítorí ìyà náà óo pọ̀.
33 Ìyà óo jẹ ọ́ lọpọlọpọ,ìbànújẹ́ óo sì dé bá ọ.N óo mú ìpayà ati ìsọdahoro bá ọ,bí mo ṣe mú un bá Samaria, ẹ̀gbọ́n rẹ.
34 O óo jìyà ní àjẹtẹ́rùn,tóbẹ́ẹ̀ tí o óo máa fi àkúfọ́ àwo ìyà tí o bá jẹ ya ara rẹ lọ́mú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
35 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí pé o ti gbàgbé mi, o sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, o óo jìyà ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ.”
36 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan ṣé o óo dá ẹjọ́ Ohola ati Oholiba? Nítorí náà fi ìwà ìríra tí wọ́n hù hàn wọ́n.
37 Nítorí wọ́n ti ṣe àgbèrè, wọ́n sì ti paniyan; wọ́n ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn, wọ́n sì ti pa àwọn ọmọ wọn ọkunrin tí wọ́n bí fún mi, bọ oriṣa wọn.
38 Èyí nìkan kọ́ ni wọ́n ṣe sí mi, wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di eléèérí, wọ́n sì ba àwọn ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́.