Isikiẹli 43:14-20 BM

14 Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan).

15 Orí pẹpẹ náà ga ní igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ìwo mẹrin wà lára rẹ̀, wọ́n gùn ní igbọnwọ kọ̀ọ̀kan (ìdajì mita kan).

16 Orí pẹpẹ náà ní igun mẹrin, òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa) ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa).

17 Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn.

18 Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára,

19 ẹ óo fún àwọn alufaa, ọmọ Lefi, láti inú ìran Sadoku, tí wọn ń rú ẹbọ sí mi, ní akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

20 Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ.