Isikiẹli 48:18-24 BM

18 Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú.

19 Àwọn òṣìṣẹ́ ààrin ìlú tí wọ́n bá wá láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli ni yóo máa dá oko níbẹ̀.

20 Gbogbo ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½) ní òòró ati ìbú. Èyí ni àròpọ̀ ibi mímọ́ ati ilẹ̀ ti gbogbo ìlú náà.

21 Ilẹ̀ tí ó kù lápá ọ̀tún ati apá òsì ilẹ̀ mímọ́ náà, ati ti ìlú yóo jẹ́ ti ọba. Ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí ilẹ̀ mímọ́ pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ati ibi tí ilẹ̀ mímọ́ náà pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilẹ̀ mímọ́ ati tẹmpili mímọ́ yóo sì wà láàrin rẹ̀.

22 Ilẹ̀ àwọn ọmọ Lefi ati ilẹ̀ gbogbo ìlú yóo wà láàrin ilẹ̀ ọba. Ilẹ̀ ọba yóo wà láàrin ilẹ̀ Juda ati ti Bẹnjamini.

23 Ní ti àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Bẹnjamini yóo ní ìpín kan.

24 Ìpín ti Simeoni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Bẹnjamini, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.