Isikiẹli 48:9-15 BM

9 Òòró ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ (kilomita 10).

10 Èyí yóo jẹ́ ilẹ̀ fún ibi mímọ́ mi, níbẹ̀ sì ni ìpín ti àwọn alufaa yóo wà, yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ní ìhà àríwá, ní ìwọ̀ oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), ní ìlà oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), òòró rẹ̀ ní ìhà gúsù yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½). Ibi mímọ́ OLUWA yóo wà ní ààrin rẹ̀.

11 Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ.

12 Lọ́tọ̀ ni a óo fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn. Yóo jẹ́ ìpín tiwọn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ilẹ̀ mímọ́ jùlọ; yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ti àwọn ọmọ Lefi.

13 Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5).

14 Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni.

15 Èyí tí ó kù lára ilẹ̀ náà tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), tí òòró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), yóo wà fún lílò àwọn ará ìlú, fún ibùgbé ati ilẹ̀ tí ó yí ìlú ká. Láàrin rẹ̀ ni ìlú yóo wà.