Isikiẹli 6:5-11 BM

5 N óo da òkú ẹ̀yin ọmọ Israẹli sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín, n óo sì fọ́n egungun yín ká níbi pẹpẹ ìrúbọ yín.

6 Ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, àwọn ìlú yín yóo di ahoro, àwọn ibi ìrúbọ yín yóo di òkítì àlàpà, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn pẹpẹ oriṣa yín yóo di ahoro ati àlàpà. A óo fọ́ àwọn ère oriṣa yín, a óo pa wọ́n run, a óo wó pẹpẹ turari yín, iṣẹ́ yín yóo sì parẹ́.

7 Òkú yóo sùn lọ bẹẹrẹ láàrin yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

8 “ ‘Sibẹsibẹ n óo dá díẹ̀ sí ninu yín; kí ẹ lè ní àwọn tí yóo bọ́ lọ́wọ́ ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nígbà tí ẹ bá fọ́n káàkiri ilé ayé.

9 Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn.

10 Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA, ati pé kì í ṣe pé mo sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ẹnu lásán pé n óo ṣe wọ́n níbi.’ ”

11 OLUWA Ọlọrun ní: “Ẹ káwọ́ lérí kí ẹ máa fi ẹsẹ̀ janlẹ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Háà! Ó mà ṣe o!’ Ogun ati ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa ilé Israẹli nítorí ìwà ìríra wọn.