Isikiẹli 8:12-18 BM

12 OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ”

13 Ó tún sọ fún mi pé, “N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn tí ó jù báyìí lọ tí wọn ń ṣe hàn ọ́.”

14 Nígbà náà ni ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá ilé OLUWA. Wò ó, mo rí àwọn obinrin kan níbẹ̀, tí wọ́n jókòó, tí wọn ń sunkún nítorí Tamusi.

15 Ó sì bi mí pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? O óo tún rí nǹkan ìríra tí ó ju èyí lọ.”

16 Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn.

17 Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn.

18 Nítorí náà, n óo bínú sí wọn, n kò ní fojú fo iṣẹ́ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. Wọ́n ìbáà máa kígbe sí mi létí, n kò ní dá wọn lóhùn.”