Isikiẹli 9:1-7 BM

1 Lẹ́yìn náà, Ọlọrun kígbe sí mi létí, ó ní, “Ẹ súnmọ́bí, ẹ̀yin tí ẹ óo pa ìlú yìí run, kí olukuluku mú nǹkan ìjà rẹ̀ lọ́wọ́.”

2 Wò ó! Mo bá rí àwọn ọkunrin mẹfa kan tí wọn ń bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà òkè tí ó kọjú sí ìhà àríwá. Olukuluku mú ohun ìjà tí ó fẹ́ fi pa eniyan lọ́wọ́. Ọkunrin kan wà láàrin wọn tí ó wọ aṣọ funfun, ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. Wọ́n wọlé, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

3 Ògo Ọlọrun Israẹli ti gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu tí ó wà, ó dúró sí àbáwọlé. Ó ké sí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́.

4 OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.”

5 Mo sì gbọ́ tí ó wí fún àwọn yòókù pé: “Ẹ lọ káàkiri ìlú yìí, kí ẹ máa pa àwọn eniyan. Ẹ kò gbọdọ̀ dá ẹnikẹ́ni sí, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú ẹnikẹ́ni.

6 Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA.

7 Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di aláìmọ́, ẹ kó òkú eniyan kún gbọ̀ngàn rẹ̀, kí ẹ sì bọ́ síta.” Wọ́n bá bẹ́ sí ìgboro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn eniyan láàrin ìlú.