Isikiẹli 9:4-10 BM

4 OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.”

5 Mo sì gbọ́ tí ó wí fún àwọn yòókù pé: “Ẹ lọ káàkiri ìlú yìí, kí ẹ máa pa àwọn eniyan. Ẹ kò gbọdọ̀ dá ẹnikẹ́ni sí, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú ẹnikẹ́ni.

6 Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA.

7 Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di aláìmọ́, ẹ kó òkú eniyan kún gbọ̀ngàn rẹ̀, kí ẹ sì bọ́ síta.” Wọ́n bá bẹ́ sí ìgboro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn eniyan láàrin ìlú.

8 Bí wọ́n ti ń pa àwọn eniyan, tí èmi nìkan dá dúró, mo dojúbolẹ̀, mo kígbe. Mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o óo pa gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Israẹli nítorí pé ò ń bínú sí Jerusalẹmu ni?”

9 Ó dá mi lóhùn, ó ní: “Ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli ati ti Juda pọ̀jù. Ilẹ̀ náà kún fún ìpànìyàn, ìlú yìí sì kún fún ìwà àìṣẹ̀tọ́. Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA ti kọ ilẹ̀ yìí sílẹ̀, kò sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.’

10 N kò ní mójú fo ọ̀rọ̀ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. N óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn lé wọn lórí.”