Àìsáyà 61:1-7 BMY

1 Ẹ̀mí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà lára minítorí Olúwa ti fi àmì-òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn talákà.Ó ti rán mi láti ṣe àwòtan oníròbìnújẹ́láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùnàti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

2 Láti kéde ọdún ojúrere Olúwaàti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3 àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónìláti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú,òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́,àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn.A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo,irúgbìn Olúwaláti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4 Wọn yóò tún àwọn ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́tijọ́ náà bọ̀ sípò;wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padàtí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdèàti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

7 Dípò àbùkù wọnàwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po-méjì,àti dípò àbùkù wọnwọn yóò yọ̀ nínú ìníi wọn;bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ ti wọn.