9 N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín.
10 Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
11 Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín.
12 Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.”
13 Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?”
14 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
15 “Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’