Isikiẹli 26:16-21 BM

16 Gbogbo àwọn ọba ìlú etí òkun yóo sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn óo bọ́ aṣọ ìgúnwà wọn, ati agbádá ọlọ́nà tí wọ́n wọ̀, jìnnìjìnnì óo dà bò wọ́n, wọn óo jókòó sórí ilẹ̀, wọn óo bẹ̀rẹ̀ sí máa gbọ̀n, ẹnu óo sì yà wọ́n nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ.

17 Wọn yóo wá dá orin arò fún ọ pé:Wò ó bí o ti parẹ́ ninu òkun,ìwọ ìlú olókìkí,ìwọ ìlú tí ó lágbára lórí òkun,ìwọ ati àwọn tí ń gbé inú rẹ,àwọn tí wọn ń mú kí ẹ̀rù rẹ máa ba àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀.

18 Àwọn erékùṣù yóo wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.Nítòótọ́, àwọn erékùṣù tí wọ́n wà ninu òkun yóo dààmú nítorí ìparun rẹ.”

19 OLUWA Ọlọrun ní, “Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ìparun bí àwọn ìlú tí ẹnìkan kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi òkun bò ọ́ mọ́lẹ̀, tí ibú omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀,

20 n óo fà ọ́ lulẹ̀ lọ bá àwọn ẹni àtijọ́ tí wọ́n wà ninu ọ̀gbun. N óo mú kí o máa gbé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bí ìlú àwọn tí wọ́n ti ṣègbé nígbà àtijọ́, ati àwọn tí wọ́n ti lọ sinu ọ̀gbun; kí ẹnikẹ́ni má baà gbé inú rẹ mọ́, kí o má sì sí lórí ilẹ̀ alààyè mọ́.

21 N óo mú òpin tí ó bani lẹ́rù dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́; bí ẹnikẹ́ni tilẹ̀ ń wá ọ, ẹnìkan kò ní rí ọ mọ́ títí lae. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”