1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli:
2 OLUWA ní,“Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run,bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn,
3 nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn.Wọn á gé igi ninu igbó,agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ.
4 Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀,kí ó má baà wó lulẹ̀.
5 Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí,wọn kò lè sọ̀rọ̀,gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọnnítorí pé wọn kò lè dá rìn.Ẹ má bẹ̀rù wọnnítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.”
6 OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba,agbára orúkọ rẹ sì pọ̀.