16 Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú.Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè,níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀.Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀,yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu,yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri.
17 Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́,ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín.N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,omi yóo sì máa dà lójú mi,nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn.
18 Wí fún ọba ati ìyá ọba pé,“Ẹ sọ̀kalẹ̀ lórí ìtẹ́ yín,nítorí adé yín tí ó lẹ́wà ti ṣí bọ́ sílẹ̀ lórí yín.”
19 Wọ́n ti sé ìlẹ̀kùn odi àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbukò sì sí ẹni tí yóo ṣí wọn.A ti kó gbogbo Juda lọ sí ìgbèkùn,gbogbo wọn pátá ni a ti kó lọ.
20 Ẹ gbé ojú sókè,kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá.Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà,àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà?
21 Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?
22 Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,tí a sì jẹ yín níyà.