Jeremaya 14:11-17 BM

11 OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.

12 Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.”

13 Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.”

14 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ.

15 Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run.

16 Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.”

17 OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé,‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru,kí ó má dáwọ́ dúró,nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi.