19 OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni?Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ?Kí ló dé tí o fi lù wá,tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn?À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé.À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí.
20 OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa,ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa,nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.
21 Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ,má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo.Ranti majẹmu tí o bá wa dá,ranti, má sì ṣe dà á.
22 Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn,ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀?Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò?OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni?Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé,nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.