5 Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,nítorí kò sí koríko.
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè,wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko.Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko.
7 Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé,‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa,sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá.Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ,a ti ṣẹ̀ ọ́.
8 Ìwọ ìrètí Israẹli,olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?
9 Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;bí alágbára tí kò lè gbani là?Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,má fi wá sílẹ̀.’ ”
10 OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
11 OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.