10 Mo gbé! Ìyá mi, kí ló dé tí o bí mi, èmi tí mo di oníjà ati alárìíyànjiyàn láàrin gbogbo ìlú! N kò yá ẹnikẹ́ni lówó, bẹ́ẹ̀ n kò yáwó lọ́wọ́ ẹnìkan, sibẹsibẹ gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣépè lé mi.
11 Kí èpè wọn mọ́ mi, OLUWA, bí n kò bá sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere níwájú rẹ, bí n kò bá gbadura fún àwọn ọ̀tá mi ní àkókò ìyọnu ati ìdààmú wọn.
12 Ǹjẹ́ ẹnìkan lè ṣẹ́ irin, pàápàá, irin ilẹ̀ àríwá tí wọn fi idẹ lú?
13 OLUWA bá dáhùn pé, “Nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, n óo fi ọrọ̀ ati ohun ìṣúra rẹ fún àwọn tí ń kó ìkógun ní gbogbo agbègbè rẹ, láìgba owó lọ́wọ́ wọn.
14 N óo mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò dé rí. Mo ti fi ibinu dá iná kan, ó ti ràn, yóo máa jó ọ, kò sì ní kú laelae.”
15 Mo bá dáhùn pé, “OLUWA, ṣebí ìwọ náà mọ̀? Ranti mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́. Gbẹ̀san mi lára àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni sí mi. Má mú mi kúrò nítorí ojú àánú rẹ. Ranti pé nítorí rẹ ni wọ́n ṣé ń fi mí ṣẹ̀sín.
16 Nígbà tí mo rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nǹkan ayọ̀ ni ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fún mi, ó sì jẹ́ ìdùnnú ọkàn mi. Nítorí orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun.