17 N óo fọ́n wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn.Ẹ̀yìn ni n óo kọ sí wọn lọ́jọ́ àjálù,wọn kò ní rí ojú mi.”
18 Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.”
19 Mo bá gbadura pe,“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA,kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi.
20 Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere?Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi.Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere,kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn.
21 Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn,kí ogun pa wọ́n,kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó,kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn,kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun.
22 Kí igbe ẹkún ó sọ ninu ilé wọn,nígbà tí o bá mú àwọn apanirun wá sórí wọn lójijì;nítorí pé wọ́n wa kòtò láti mú mi,wọ́n dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi.
23 OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀,o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí.Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n,má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ.Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ,nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.”