6 “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.
7 Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run,
8 bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró.
9 Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀;
10 bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró.
11 Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe.
12 Ṣugbọn wọ́n ń wí pé, ‘Rárá o, OLUWA kàn ń sọ tirẹ̀ ni, tinú wa ni a óo ṣe, olukuluku yóo máa lo agídí ọkàn rẹ̀.’ ”