1 OLUWA sọ fún mi pé,
2 “Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí.
3 Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWAÒun ni àkọ́so èso rẹ̀.Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi;ibi sì dé bá wọn.Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”
4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli.
5 OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán?
6 Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà,ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti,tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já,ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun,ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri,ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá,tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?