1 OLUWA sọ fún mi pé, kí n lọ sí ilé ọba Juda kí n sọ fún un níbẹ̀ pé,
2 “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé:
3 Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí.
4 Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan.