23 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni,tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari.Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín,tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ!
24 OLUWA sọ fún Jehoiakini ọba, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pé, “Mo fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni òrùka èdìdì ọwọ́ ọ̀tún mi,
25 n óo bọ́ ọ kúrò, n óo sì fi ọ́ lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ati àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ, tí ẹ̀rù wọn sì ń bà ọ́.
26 N óo wọ́ ìwọ ati ìyá tí ó bí ọ jù sí ilẹ̀ àjèjì, tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí ọ sí, ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí.
27 Ṣugbọn ilẹ̀ tí ọkàn yín fẹ́ pada sí, ẹ kò ní pada sibẹ mọ́.”
28 Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini?Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì?Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí?
29 Ilẹ̀! Ilẹ̀!Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ!