Jeremaya 23:13-19 BM

13 Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria:Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà.

14 Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu:Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn,wọ́n ń hùwà èké;wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀.Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi,àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora.

15 Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé:N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ,n óo fún wọn ní omi májèlé mu.Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmuni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.

16 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ.

17 Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.”

18 Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́?

19 Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú.