16 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ.
17 Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.”
18 Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́?
19 Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú.
20 Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.”
21 OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
22 Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.