34 Bí wolii kan tabi alufaa kan tabi ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan wọnyi bá wí pé òun ń jẹ́ iṣẹ́ OLUWA, n óo jẹ olúwarẹ̀ ati ilé rẹ̀ níyà.
35 Báyìí ni kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa wí fún ẹnìkejì rẹ, ati fún arakunrin rẹ̀, “Kí ni ìdáhùn OLUWA?” tabi “Kí ni OLUWA wí?”
36 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa.
37 Bí ẹ óo ti máa bèèrè lọ́wọ́ àwọn wolii ni pé, “Kí ni ìdáhùn tí OLUWA fún ọ?” Tabi, “Kí ni OLUWA wí?”
38 Ṣugbọn bí ẹ bá mẹ́nu ba “Ẹrù OLUWA,” lẹ́yìn tí mo ti ranṣẹ si yín pé ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nu bà á mọ́,
39 tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè, n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín.
40 N óo mú ẹ̀gàn ati ẹ̀sín ba yín, tí ẹ kò ní gbàgbé títí ayérayé.