Jeremaya 23:8-14 BM

8 ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

9 Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii,gbogbo ara mi ń gbọ̀n.Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó,mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa,nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.

10 Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn,ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀,wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹgbogbo pápá oko ló ti gbẹ.

11 Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù,ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

12 Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn,a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú,nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn.

13 Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria:Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà.

14 Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu:Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn,wọ́n ń hùwà èké;wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀.Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi,àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora.