Jeremaya 25:28-34 BM

28 Bí wọn bá kọ̀ tí wọn kò gba ife náà lọ́wọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, wí fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní wọ́n gbọdọ̀ mu ún ni!

29 Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

30 “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé:‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè,yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀.Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀.Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.

31 Ariwo náà yóo kàn dé òpin ayé,nítorí pé OLUWA ní ẹjọ́ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè rò.Yóo dá gbogbo eniyan lẹ́jọ́,yóo fi idà pa àwọn eniyan burúkú,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

32 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ibi yóo máa ṣẹlẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, ìjì ńlá yóo sì jà láti òpin ayé wá.

33 Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀.

34 Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa.