Jeremaya 27:10-16 BM

10 Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín, wọ́n fẹ́ kí á ko yín jìnnà sí ilẹ̀ yín ni. N óo le yín jáde; ẹ óo sì ṣègbé.

11 Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12 Iṣẹ́ yìí kan náà ni mo jẹ́ fún Sedekaya ọba Juda. Mo ní, “Fi ọrùn rẹ sinu àjàgà ọba Babiloni, kí o sin òun ati àwọn eniyan rẹ̀, kí o lè wà láàyè.

13 Kí ló dé tí ìwọ ati àwọn eniyan rẹ fẹ́ kú ikú idà, ikú ìyàn ati ikú àjàkálẹ̀ àrùn bí OLUWA ti wí pé yóo rí fún orílẹ̀-èdè tí ó bá kọ̀ tí kò bá sin ọba Babiloni?

14 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń wí fun yín pé ẹ kò ní ṣe ẹrú ọba Babiloni, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.

15 OLUWA ní òun kò rán wọn níṣẹ́. Wọ́n kàn ń fi orúkọ òun sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni, kí òun lè le yín jáde, kí ẹ sì ṣègbé, àtẹ̀yin àtàwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín.”

16 Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.