8 Àwọn wolii tí wọ́n ti wà ṣáájú èmi pẹlu rẹ ní ìgbà àtijọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn nípa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati nípa àwọn ìjọba ńláńlá.
9 Wolii tí ó bá fẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé alaafia yóo wà, nígbà tí ọ̀rọ̀ wolii náà bá ṣẹ ni a óo mọ̀ pé OLUWA ni ó rán an níṣẹ́ nítòótọ́.”
10 Hananaya wolii bá bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, ó sì ṣẹ́ ẹ.
11 Hananaya bá sọ níṣojú gbogbo eniyan pé OLUWA ní bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣẹ́ àjàgà Nebukadinesari ọba Babiloni kúrò lọ́rùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè kí ọdún meji tó pé. Wolii Jeremaya bá bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.
12 Lẹ́yìn tí Hananaya wolii bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, tí ó sì ṣẹ́ ẹ, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,
13 “Lọ sọ fún Hananaya pé OLUWA ní àjàgà igi ni ó ṣẹ́, ṣugbọn àjàgà irin ni òun óo fi rọ́pò rẹ̀.
14 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti fi àjàgà irin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọnyi kí wọn lè di ẹrú Nebukadinesari ọba Babiloni, kí wọn sì máa sìn ín, nítorí òun ti fi àwọn ẹranko inú igbó pàápàá fún un.”