14 Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
15 “Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’
16 Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn,
17 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’
18 Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ.
19 Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo.
20 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’