Jeremaya 29:17-23 BM

17 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’

18 Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ.

19 Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo.

20 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’

21 “Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín.

22 Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’

23 nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.”