23 nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.”
24 OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé,
25 “Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé:
26 “Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn.
27 Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí.
28 Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.”
29 Sefanaya Alufaa ka ìwé náà sí etí Jeremaya wolii.