11 Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀.
12 Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé:‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí.N kò ní máa bínú lọ títí lae.
13 Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,lábẹ́ gbogbo igi tútù;o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’
14 “Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.
15 N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín.
16 Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀
17 Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́.