Jeremaya 3:13-19 BM

13 Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,lábẹ́ gbogbo igi tútù;o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’

14 “Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.

15 N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín.

16 Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀

17 Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́.

18 Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.”

19 OLUWA ní,“Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi,tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára,kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù,láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ,ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.