1 OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli,tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.
2 Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀;nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi,
3 OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè.Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ,nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.
4 N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú.
5 Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria;àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀.
6 Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé,‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni,sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ”