Jeremaya 31:6-12 BM

6 Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé,‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni,sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ”

7 OLUWA ní,“Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu,kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé,‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ lààní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’

8 Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,n óo kó wọn jọ láti òpin ayé.Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn,ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́.Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí.

9 Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá,tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada.N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn,lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ;nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.”

10 OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré;ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ,yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’

11 Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada,yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ.

12 Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni,wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn:Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró,ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù;ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́.