10 Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!”
11 A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù.
12 Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́.
13 Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì.Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ.A gbé, nítorí ìparun dé bá wa.
14 Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ,kí á lè gbà ọ́ là.Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?
15 Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani,tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu.
16 Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀,kéde fún Jerusalẹmu pé,àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè.Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda.