11 Ẹ má bẹ̀rù ọba Babiloni tí ẹrù rẹ̀ ń bà yín, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo gbà yín là n óo sì yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀.
12 N óo ṣàánú yín, n óo jẹ́ kí ó ṣàánú yín, kí ó sì jẹ́ kí ẹ máa gbé orí ilẹ̀ yín.’
13 “Bí ẹ bá wí pé ẹ kò ní dúró ní ilẹ̀ yìí, tí ẹ kò sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu;
14 bí ẹ bá ń wí pé, ‘Rárá o, a óo sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a kò ti ní gbúròó ogun tabi fèrè ogun, níbi tí ebi kò ti ní pa wá, a óo sì máa gbé ibẹ̀,’
15 ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí ẹ bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti, pé ẹ óo lọ máa gbé ibẹ̀, ogun tí ẹ̀ ń sá fún yóo bá yín níbẹ̀;
16 ìyàn tí ẹ̀ ń bẹ̀rù yóo tẹ̀lé yín lọ sí Ijipti; ebi tí ẹ páyà rẹ̀ yóo gbá tẹ̀lé yín, ibẹ̀ ni ẹ óo sì kú sí.
17 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti láti máa gbé ibẹ̀ yóo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, wọn kò ní ṣẹ́kù, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni wọn kò ní bọ́ ninu ibi tí n óo mú wá sórí wọn.’