Jeremaya 49:14-20 BM

14 Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n ní kí wọn kéde pé,“OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu,ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í!

15 Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeréláàrin àwọn orílẹ̀-èdè,o óo sì di yẹpẹrẹ,láàrin àwọn ọmọ eniyan.

16 Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta,tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé.Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì,n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

17 OLUWA ní, “Edomu yóo sì di ibi àríbẹ̀rù, ẹ̀rù yóo máa ba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba ibẹ̀ kọjá, wọn yóo máa pòṣé nítorí ibi tí ó dé bá a.

18 Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19 Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn.