1 Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu,wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀!Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan,tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́,tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu.
2 Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,”sibẹ èké ni ìbúra wọn.
3 OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́?Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n,o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí.Ojú wọn ti dá, ó le koko,wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada.
4 Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé,“Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí,wọn kò gbọ́n;nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA,ati òfin Ọlọrun wọn.
5 N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki,n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀;nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA,ati òfin Ọlọrun wọn.”Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá,tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA.
6 Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀.Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run.Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn,tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú,yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀,nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun.