14 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,iná yóo sì jó wọn run.
15 Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli,mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè,tí yóo ba yín jà.Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà,orílẹ̀-èdè alágbára ni.Ẹ kò gbọ́ èdè wọn,ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ.
16 Apó ọfà wọn dàbí isà òkú tó yanu sílẹ̀,alágbára jagunjagun ni gbogbo wọn.
17 Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ,wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ,wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin.Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín,ati àwọn mààlúù yín.Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín.Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.”
18 OLUWA ní, “Ṣugbọn sibẹ, ní gbogbo àkókò yìí, n kò ní pa yín run patapata,
19 nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”
20 OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda: