19 nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”
20 OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda:
21 Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n,ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran;ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn.
22 Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín?Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè.Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun,tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé!Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan,kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.
23 Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín.Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ.
24 Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé:‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa,tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀,ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn;OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́,tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’
25 Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada,ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín.