24 Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé:‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa,tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀,ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn;OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́,tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’
25 Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada,ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín.
26 “Àwọn eniyan burúkú wà láàrin àwọn eniyan mi,wọ́n ń dọdẹ eniyan bí ẹni dọdẹ ẹyẹ,wọ́n dẹ tàkúté, wọ́n fi ń mú eniyan.
27 Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀,bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ.Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá,wọ́n di olówó,
28 wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán.Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà.Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba,kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà;wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní,kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́.
29 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí?
30 Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu,ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà: